Iyeru-Okin, Omo Olofa Mojo, Omo Olalomi, Omo abisu Joruko , ijakadi loro toffa toffa, Ija kan ijakan ti won nja lofa lojosi, Olalomi oju talose, Osoju ebe lala, O si soju poro ninu oko, Ibasoju oloko, iba lawon, Omo ‘laare, Omo bu re, ikan o gbodo ju kan, Bi kan ba ju kan nile olofamojo ogun lon’da ni ile baba wan, Omo omaka, Omo osa oje ba mi ki anomo. Omo olalomi ni mori, Mo dasa lami lapa, Iyeru okin ni mori, Mo dasa lami lobe, Mi o pe e mo lami sugbon, E mo je ko jinle lapa mi, Ijakadi loro ofa.